EEGUN OLOKIKI NI LAWARIKO JE LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN.
LAWARIKO je Eegun lati ilu Owu ni Abeokuta ni ipinle Ogun. Ale ni Eegun
yi ma a njade nigbati
gbogbo awon eniyan ba n sun. Eekan ni odun meta ni
o ma a n jade. Ki o to di ojo ti o ma a jade nigbati won ba n se odun
fun un, won a ti toju owo lati wa jije ati mimu fun awon eniyan ti won n
bo wa ba won se odun. Ojo agan LAWARIKO ma n dun pupo nitori o ma a n
kun fun ijo ati ayo. Awon obinrin ko gbodo ri Eegun LAWARIKO ayafi awon
okunrin to lagbara ni won ma a n wa pelu re. Ohun ti o je pataki nipa
Eegun LAWARIKO ni wipe jijade re ma a fo ilu mo daradara. Biotileje wipe
awon obinrin ko gbodo ri soju, sugbon gbogbo adura ti o ba se fun won
ati jijade re ma a ni ipa ni ilu. Eegun LAWARIKO je ebun n la pataki ti
awon baba n la wa fun wa fun asa ati ise ile wa. Atipe oju ona ti awon
baba nla wa fi fun wa ni yi.
AWON ONA LORISIRISI TI IKOKO FI WULO Lati Owo Olalekan Oduntan.
Ikoko alamo ni awon baba nla wa fi n pon omi si fi se gbogbo awon ise
ile ni aye atijo. Koda bi oju ti la to ni ode oni yi, awon ti won si n
fi ikoko alamo pon omi mimu sile wa daada ni aarin ilu ati awon igberiko
wa kaakiri. Ni aye atijo, won a ma a fi ikoko alamo se obe. Obe ti won
ba fi se, a ma a dun pupo. Omi ti won ba a fi ikoko alamo pon a ma a
tutu bi omi inu ero amomitutu. Awon iya wa ni aye ojohun a ma a ro oka
ninu ape tabi te eba ninu re. Won a si tun ma a ro eko pipon sewe ninu
re. Bi ikoko ti wulo fun wiwa ounje ni o tun wulo fun awon ti o n se ise
isegun ati awon Babalawo nitoriwipe won a ma a lo ikoko fun gbigbe ebo
fun awon irunmole laajin. Won a si tun ma a fi se agbo lorisirisi fun
awon alaisan ti won n toju. Awon alaro naa a ma a da aro sinu ikoko
lati fi re aso fun awon eniyan. Amo ni won fi nse ikoko. Leyinti won ba
ti mo won kale lorisiri tan, won a sa won ki o won gbe daradara, ki won
to wa lo fi won ra ina lati le jeki won gbe daradara si. Ise ikoko ma a n
mu ere to po wa fun awon ti won n se e. O si je asa ati ise wa ni ile
Yoruba.
ILA KIKO JE OHUN IDANIMO AWON
YORUBA Lati owo Olalekan Oduntan
 |
AWON ILA ILE YORUBA: KEKE, ABAJA, BAMU, GOMBO ATI PELE |
Ila kiko je n kan pataki ti
awon omo Yoruba fi n dara won mo ni aye ajo. Owe Yoruba kan so pe tita riro ni
a n ko ila, sugbon bi o ba jina tan, a di oge. Ni aye atijo, oba Alaafin Oyo ma
a n fi ila kiko se ohun ijiya fun awon eru re ti won ba ti se asise. A a ni ki
awon oloola ko ila fun won gegebi ohun ijiya fun won. Sugbon ni ojo kan,
leyinti won ti ko ila si gbogbo ara eru kan tan,
 |
ARABINRIN RASHEEDAT YUSUF |
nse ni gbogbo awon obinrin ti
o wa laafin ati awon olori oba da oju bo eru naa. Won ri bi ila ara re se jeki
o rewa si, ti o nda gbogbo won lorun. Eyi bi Alaafin ninu pupo, o si pa lase
wipe enikeni ko gbodo ko iru ila bee yen mo ayafi idile oba nikan. Oro naa di
ase lati igba naa lo. Idi niyi ti o fi je wipe enikeni ti o ba ko ila, idile
oba ni o ti wa, ti ko ba je ti oba Alaafin ni Oyo, a je ti oba ile Yoruba
miran, nitoriwipe idile oba ati awon ijoye ni ila kiko ti fan kaakiri ile kaaro
o jire. Ila kiko je ona ti awon omo Yoruba ngba a sami si nkan lara, won a tun
ma a lo lati fi se oge si ara won. Ki o to wa di ohun asa kaakiri gbogbo agbaye
lode oni fun awon Oyinbo, ila kiko ni won wo fi se arikose fun ara won. Gegebi
mo ti so ni ibere oro mi wipe orisirisi ila ni o wa ni ile Yoruba. A o se alaye
lorisirisi nipa awon ila naa.
Ila akoko ni won npe ni ABAJA MEFA-MEFA, kiko ila yi je mefa mefa ni ibu
leeke eniti won ba ko fun. Awon idile oba Alaafin ni Oyo ni o ma a n ko o.
Eyiti o tun tele ni PELE META-META, kiko ila yi je meta meta ni ooro leeke
eniti won ba ko fun. Idile awon Eleegun ni won ti ma a n ko ila naa. Eleyi ti o
tun tele ni GOMBO MEJE MEJE AWADORI. Won a maa ko ila yi lati oke egbe ori wa
si ereke bi igbati won ko leta" L" leemeta, ti won wa ko Ila merin
toku le "L" yen lori. Ila ti o tun tele ni PELE kookan looro leeke
mejeeji ti awon ti o wa lati ilu ONDO maa n ko o. Won a maa pe oruko re ni ila
ONDO. Eyiti a tun mo ni IIa ABAJA MEJE MEJE. Eleyi je IIa merin looro ati meta
lori re ni ibu. Awon omo iIu Oyo ati Kwara ni won maa n ko IIa yi. Won a tun
maa pe IIa kan ni MERIN MERIN. IIa yi je merin merin ni ibu leeke mejeeji. Awon
omo ilu Ibadan ni o maa nko o. IIa ti o tun wa ni ile Yoruba ni won npe ni
KEKE. Won a ma a ko lati egbe oke ori de isale ereke mejeeji. Awon omo ilu
Ibadan ati Oyo ni ma a n ko o. IIa kan a tun ma a je BAMU. Won a ma a ko Ila yi
si oke ori imu lotun ati losi. Awon ara ilu Tapa ni o ma a n ko ila naa. Awon
Oloola ni won ma a n ko IIa pelu abe, won a si ma a tele ohun ilana idile
enikeni ti won ba fe ko o fun. Ti won ba a ti ko ila tan, omi igbin ni won ma a
n to si loju titi ti yo o fi jina. Bio tile je wipe IIs kiko ni ile Yoruba ti n
di ohun ti o n pare, asa ati ise awa omo Yoruba ni, ohun ni o si fi omo Yoruba
tooto han.
 |
ABAJA OYO MEJE MEJE | |
 |
ABAJA ILORIN MEJE MEJE | |
EJI OGBE BABA IFA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
 |
OLALEKAN ODUNTAN |
Ninu awon odu
merindinlogun ti won je owo Ifa, Ejiogbe ni baba won. Ejiogbe ni odan ni n
sawo won ninu ile, iki ni n sawo won lode. O ni kekere la a ti pile awon, to
ba doke tan, a gbodo, a gbolo, a gba odu baba ikoko. O difa fun aye nigbati
aye n sunkun alailenikan, won ni ki aye wa a san. Lojo naa, awon ohun merin
lo wa nile aye. Ekinni ni Ile, ekeji ni Omi, eketa ni Afefe ati eekerin ni o
je Ina. Awon mererin pe Eledumare lojo kan wipe awon fe wulo ati ni ipa nile
aye. Eledumare ni ki won san eku meji oluwere, eja meji
 |
ODU EJI-OGBE |
abirugbede, obidiye
meji abedo lukeluke. Ni won ba rubo, lebo ba fin, lebo ba da. Ohun ni
Eledumare ba fun erupe nile aye. Ati igba naa wa nile aye ti n be. Ile aye wa
n be bee, sugbon nigbati o di ojo kan, aye so fun Olodumare wipe ohun fe e
nipa, Olodumare ni a fi ko san eku meji oluwere, eja meji abirugbede,
obidiye meji abedo lukeluke. O rubo,
ebo fin ebo da, Eledumare wa mu erupe o fi da akoda. Akoda naa tun pe
Eledumare lojo kan wipe ohun fe lenikeji ti yo ma ran ohun lowo. Eledumare ni
ki o san eku meji oluwere, eja meji abiru gbede, obidiye meji abedo lukeluke. O san ebo fin beeni ebo da. Eledumare wa mu ninu eegun egbe otun akoda fi da
aseda. Akoda ati aseda wa n be laye, igbati o di ojo kan, awon naa tun pe
Eledumare wipe awon fe ni ipa omo bibi laye. Eledumare ni ki won san eku meji
oluwere, eja meji abirugbede, obidiye meji abedo lukeluke. Won gbo riru ebo,
won rubo, ebo won fin ebo won si da pelu. Akoda ati Aseda ba ara won se papo, aseda ba loyun o bi opolopo awon omo fun akoda. Won bi funfun, dudu, pupa
ati ayinrin. Ati igba naa ni a ti n juba akoda ati aseda. Bi itan Ejiogbe se lo niyi ni oju ona Ifa olokun
asoro ekun dayo. Elaboru elaboye!!!
FIFI IKIN DA IFA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
 |
IKIN IFA Kini won n pe ni
Ikin? Ekuro ti won mu lati ara eyin ope ni. Lati ara eyin ope yi naa ni won ti n
se epo pupa jade. Ikin ni Orunmila ma a fi n difa ni igba iwase ki o to di wipe
Opele de. Ki i se wipe Opele ko riran daradara bi Ikin sugbon iyato to wa nibe
ni wipe babalawo nikan ni o le ni Opele lowo lati fi ma a difa fun awon eniyan. Gbogbo eniyan ni o le ni Ifa ti a ba fi Ikin da ni ile won. lnu awo olomori
funfun ni awon babalawo ma a n da Ifa si fun enikeni ti o ba fe ni nile. Bi won
ba fe wo akosejaye fun enikeni, Ikin ni awon babalawo yo o fi wo. Ekuro yi ni won
yo ma mi ni owo won ti won yo si ma fi Iyeri Osun |
 |
IKIN NINU AWO |
ko ODU IFA ti o ba jade si
ori opon Ifa. Bi ODU IFA ba ti jade ni won yo ma a ki kikankikan fun eniti
babalawo difa naa fun. Ohunkohun ti o ba yo ninu ODU IFA eni naa ni won yo o fi
bo Ifa fun un. Oti, epo, omi, pepeye tabi eran obuko ni awon babalawo ma a fi
n bo Ifa fun eniyan. Nigbamiran ohun ti Ifa yo o beere le ma gba ona yi lo
rara. Leyin igbati babalawo ba ti se gbogbo awon etutu ti o je mo ODU IFA ti o
ba jade tan, won yo da gbogbo re pada si inu awo funfun ti yo ma a wa ninu
re. Babalawo le gbe awo Ifa yi si odo re tabi ki eniti won bo Ifa fun gbe lo si
ile re. Leyin eyi ni babalawo yo ran eniti won bo Ifa fun wipe ki o ma a se
iranti lati ma a bo IFA re loore koore. Ni ipari oro mi, bi o ti je wipe eyin
ope ni ekuro ti awon babalawo ma n lo fun Ikin, inu eyin ope naa ni epo pupa ti
won n lo pelu Ikin ti jade. Idi niyi ti epo pupa se ma a n wa ninu Ikin ti won
fi bo Ifa. Iyeri osun ti babalawo fi ko
Odu Ifa sile naa yo o lo sinu awo Ifa pelu.
OUNJE OMO ENIYAN ATI ORISA NI ISU JE LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
 |
ARABIRIN LATEEFAT AKINPELU
|
 |
ISU BENUE |
Lati aimoye odun
gbooro seyin ni isu ti wa laye. O de je
ounje ti awon eniyan nife si pupo lati ma a je. Sugbon ki i se awon omo eniyan
nikan ni won feran lati ma a je isu, orisa bi Ogun naa ma a n je e. Arabinrin
Lateefat Akinpelu ti o je gbajugbaja onisu tita fun opolopo odun seyin salaye
lorisirisi nipa awon eya isu ti o wa.O so wipe won ma a n pe isu kan ni 'Pepa'
eleyi ti o je wipe awon ara wa ni ile Hausa ni won ni isu naa. Awon ni won si
tun ma a n gbin in. Eya isu miran ti o tun wa ni isu ti won n pe ni 'isu
 |
ISU ABUJA |
Abuja'. Awon agbe Hausa naa ni won ni isu
Abuja yi i. Isu yi i dara pupo lati fi gun iyan, beeni o je olokiki laarin awon eya isu toku. Arabinrin Lateefat Akinpelu tun
so nipa awon eya miran ti won n pe ni isu Benue ti awon agbe Gara ma a n gbin.
Eya isu ti o tun tele eyi ni isu Efuru ti o je tiwa ni ile Yoruba nibi. Bi isu
yi ti dara ti o si dun to, o ti n fe
parun nitori awon agbe wa ni ile Yoruba ko fe sise agbe mo. Eleyi ni o fa ti o
fi je wipe awon agbe ni ile Hausa fi ma a wa n ta isu fun wa ni ile Yoruba nibi. Beeni igba kan si n bo ti awon
agbe wonyi ko ni wa ta isu won si ile
 |
ISU HAUSA |
Yoruba mo. Bi iru isele baayi ba sele,
nibo ni a fe wa isu gba ni ile Yoruba? Orisirisi ona ni a ma a n gba je isu. A le
fi isu gun iyan ki a si fi je obe egusi tabi ki a se ki a fi epo pupa je. Won a
tun ma a yan je pelu. Gegebi mo ti so lateyinwa wipe ki i se awa omo eniyan
nikan ni o ma n je isu, awon orisa naa ma a n je e. Gegebi apeere, won ma a n
fi iyan ati obe egusi bo orisa Ogun. Won a si tun ma a fi isu sisun bo pelu.
Arabinrin Lateefat Akinpelu ro awon ijoba wa ki won se iranlowo fun awon agbe
wa ni ile Yoruba ki isu
 |
ISU EFURU |
gbingbin ma ba a di ohun igbagbe ni ile wa. O ni bi
ijoba ba le ran won lowo pelu owo ati ajile, awon odo wa ti o n sise agbe ni
igberiko ko ni ma a sa fise agbe sile lati wa se ise alakowe ni igboro. O si
tun bee awon ijoba lati ran awon egbe onisu lowo ki won ba le ma a ri owo
sowo. O ni bi ijoba ba ya awon lowo lati fi sowo, awon yo o da owo naa pada fun ijoba pelu ere ti won ba fi le
lori nigbati awon ba fi sowo tan. Ni ipari oro mi emi naa ro awon agbe wa ni
ile Yoruba lati ma a je ki isu gbingbin parun ni ile wa nitori teni n teni,
tekisa n takitan.
OGUN FI ADA IDE RE LANA FUN ORUNMILA ATI ESU LATI OWO
OLALEKAN ODUNTAN
 |
OLOYE SHAKIRU OLUGBEMI OGUNLADE
|
Ogun bi ile lo ba wa, ko o wode, Ogun beyinkule lo ba wa, ko
o woode, Bi yaara lo ba wa, ko o wokankan ile. Ogun onire oko mi, edun
atOluweri, eegun esusu ti n Kora re lebe. Ogun le won degbo, won daara
'gbo, Ogun le won doodan, won a dero odan.
 |
OJUBO OGUN |
Ogun le won de Mekiti, won a
d'Oluweri. Ogun je alagbara okunrin nigba aye re ki o to wa di Orisa loni yi.
Nigbati Olodumare da ile aye tan, apakan ile aye je omi nigbati apa keji si je
kikida igbo kijikiji. Eledumare fe ran Orunmila ati Esu wa sile aye sugbon O n
wa Orisa ti yo o ba ohun la ona fun won. Ogun lakaaye gba lati fi ada ide owo
re la ona fun Orunmila ati Esu. Awon meteeta si pade ara won no ikorita meta ona
ti Ogun ti la. Won si bara won mule ni ojo naa. Won pe ara won ni aaro meta ti
ko gbodo da obe nu. Ogun je Orisa to so po mo irin, eleyi lo faa ti awon alagbede, awon onimoto, awon eleran, awon
kolekole, awon gbenagbena fi ma a n bo loore koore. Awon olode naa ko gbeyin
nipa bibo rara. Emu, isu sisun, agbado sisun, akuko adiye, obi abata oloju
 |
OGUNDA MEJI |
merin, aja ati oti sinaapu ni a fi ma a n bo o. Odun Ogun ma a n dun pupo
nitori orin ati ijala orisirisi ni awon emewa Ogun yo ma pe ti egbe naa yo si ma fohun si ni sise n tele. Irin maarun
ni n joye lagbede nile baba to bi mi, Emu Lolukotun, Ewiri Lajagunna,
Atemole la fi Joogbagbara, Ile Aro la fi Jeyalode, Omo Owu lo je Balogun,
Omode Ogun, e e gberin ode a be e gberin. Ogun to lorisa ode, ta n pogun o to
lorisa ko wi, Ogun to lorisa ode.
ORI BIBO NI ILE YORUBA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
 |
ABORE LUKUMON ADESANYA
|
Ori lonise, eda eni lalayanmo, Ori mi asingbara ileke, ada ni
wale aye, mase gbagbe mi, Mose bori leja
fi n la bu, Ori laponran fi n laagba iroko, Ori mi ma a pada leyin mi, gbe mi
debi ire, Bori ba n seelomii, won a leegun ni, Beleda ba n seelomii, won a si
loosa ni, Orisa bi ori o si, ori eni la ba kobi bo. Ori bibo ni ile Yoruba je
ona pataki ti a fi n ba eleda eni soro ati be ori eni. Orisa pataki kan ni a mo
Ori si laarin awon ookanlenigba irunmole. Ko si se fowo roti seyin rara. Itan
kan so ninu ese Ifa kan wipe eye ki i fo, ko gbagbe ori e sile, bi eja ji ninu
ibu, tohun tori e lo jo n ji, bi erin ba ji nigbo, tohun tori e lo jo n ji, bi
efon ba ji lodan, tohun tori e lo jo n ji. A ki i nikan sun ka a nikan ji, ba a
ba nikan sun, Olorun oba ni ji ni loju
 |
ENITO N BORI |
orun, A difa fun awon meta ti won jo sun,
akuko adiye ji eni kinni, ohun ba jawon mejeeji yoku, awon meji wa n beere lowo e
wipe, bawo lo se ji? O ni Olorun oba lo jihun loju orun. Awon igba irunmole n
binu Ori, won binu Ori tititi, won o pada leyin Ori, Ori ba binu si won o da
gbogbo won lagara. O mu Sango wole ni Koso, O mu Oya wole nile Ira, O mu Ogun
wole ni Ire ati bee bee lo. Bi ori bibo
ba yo si eniyan, Odu Ifa Odi meji ni yo jade loju opon Ifa babalawo. Won le ni ki
o fi eja aro tabi eye etu pelu omi, obi abata oloju merin, oti sinaapu ati owo
boo. Ale ni won ma a n bo ori fun eniyan. Leyin eyi, oro eniti won bori fun ti
dayo, ki ona la fun ki o si ma a gbadun lo ku. O dabo!
OMO KEKERE ONILU BATA LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
 |
OMODE ONILUU BATA |
Ilu Bata je ilu fun un awon orisa bi Sango ati Eegungun. Awon
orisa mejeji feran ilu yi debi wipe ohun ni won ma a n lu fun won nijo kijo ti
won ba ti n bo won. Ilu Bata je ilu ti o je bi merin ti o tele ra won. Akoko n
be ni Omele meta ti o ma n mu sisupo ilu duro daradara, ohun si ni gbogbo awon
ilu yoku ma a n tele. Eleyi to tele Omele meta ni won n pe ni Eejin Bata, ilu
yi ni yo o jeki ilu ni ikimii tabi ki o rinle daradara. Omole Bata ako ni o tun
tele awon mejeji yi ti won si ma n ba ara won soro ni sise n tele. Ajosepo
wonyi ma a n larinrin pupo ti awon onilu meteeta yi ba da ilu bole ni oju
agbo. Ilu Bata Isaaju ni o je oga patapata fun awon ilu ti a ti daruko seyin yi.
Ilu yi ma a n dun yato ti won ba n lu u, won a si ma fi pa owe lorisiri. Won a ma
fi ilu Bata Isaaju yi ko orin ni olokanojookan pelu ajosepo awon ilu toku ti yo
si gbale kikankikan. Bi ilu Bata se le lati lu beeni ijo re naa le lati jo.
Opolopo ijaapamonu ni o wa ninu ijo Bata. Eniti ko ba jehun kanu daradara, ko
le e jo. Awon Eelegun ati awon Eemewa Sango ni won mo ilu Bata jo daradara. Eko
pataki n la ni kiko lilu ilu Bata ati jijo ijo Bata je. Bi eniyan ba si fe mo
awon n kan wonyi, o ni lati lo si odo awon eniti o mo o fun idanileeko. Ohun kan
pataki ti mo fe ki a mo ni wipe awon OniSango ati Eleegun ni won ni ilu Bata bi
o tile je wipe ilu naa ti di ohun ti awon elesin yoku n lo ninu orin won ni ode
oni. Ipari oro mi ni wipe ohun ajogunba ninu asa wa ni ilu Bata je, e je ka
fowo sowopo ka jijo gbe laruge. Oyinbo ko le lu ilu Bata bi awa ti a ni beeni
won o si le jo si ilu Bata bi awa omo oninkan. Ohun gbogbo ti Eleda se fun wa lo
dara, awa ni o ku si lowo lati ma a fi enu gan an awon n kan wa mo! O dowo was!! O dabo!!!
MO LO SE BABA KEEPE SI BAALE SHOMOLU LAAFIN WON ,LATI OWO
OLALEKAN ODUNTAN
 |
OLOYE SALIU AKANNI JIMOH OLUNDEGUN BAALE ORILE SHOMOLU AKOKO |
 |
Baale ati Olalekan |
 |
IYA BAALE |
Laipe yi, mo lo si afin Baale Orile Shomolu akoko lati lo ki
won ku odun eegun to n lo lowo bayi, won si gba mi lalejo daradara. Oloye Saliu
Akanni Jimoh Olundegun je Baale fun orile Shomolu akoko, won si ti wa ni ori
apere baba won fun igba die seyin. Baale salaye wipe owo to po pupo ni awon
ilu ati awon oloye ma n na lati se odun
eegun, odun oro, odun igunnuko, odun eegun awon jigbo ati bee bee lo. Bi won ba ti
da ojo awon odun wonyi sona ni owo dida yo ti bere lati se awon etutu ti o ba
leto. Baale tun te siwaju ninu oro re wipe etutu sise dara ninu ilu lati le
ajakale arun wole tabi wogbo. Etutu a ma mu ohun gbogbo lo daradara ni ilu
laisi wahala kankan rara. Oloye Saliu Akanni Jimoh Olundegun ni opolopo irepo
ati alafia ni o wa laarin awon ara ilu ati awon oloye won. Ati wipe, lati igba
ti won ti di Baale ni won ti mu oro
irepo ni n kan pataki. Oloye Saliu Akanni Jimoh Olundegun je Baale keewa fun
orile Shomolu. Baale ana to waja ki awon to je ni Oloye Ishola Akinpelu Irunmu
Ekun. Awon si ni Baale keesan.
 |
AAFIN BAALE |
Baba Oloye
Saliu Olundegun funrare ni Baale keejo. Bayi ni won se n to bo ti ohun gbogbo
si n lo laisi wahala. Baale ni awon n ro ijoba lati ma ran awon elesin ibile
lowo nitori owo kekere ko ni won fi n se etutu ni ilu. Won tun te siwaju ninu
oro won wipe bi a ba se etutu ni igba to to si ilu, gbogbo daamu daabo, rukerudo,
ajakale aarun, ogun ati ote yo di ohun igbagbe ninu ilu. Oloye Saliu Akanni Jimoh je eniti ilu n fe. Won ni iyawo beeni won si bi awon omo pelu. Mo ki baba wipe ade
a pe lori, bata a pe lese, ase a pe lenu, irukere a pe lowo. E o fi owo pa
ewu, e o fi erigi je obi, e o fi opa se eketa ara. E o gbo bi Oluwonwotiriwo, e o gbo bi Oluwonwotiriwo. E o gbo bi agba kan, to dagba titi, to fi omo owu
se onde sorun. Omo owu je je je, o ku bi obe, obe je je je, o ku bi abere,
abere je je je, o ku bi iru esin. O dabo!!!
RIRU EBO NI ILE YORUBA FUN AWON ORISA LATI OWO LALEKAN
ODUNTAN
 |
ODU OSA MEJI |
Riru ebo ni n gbe ni, airu ebo ki i gbeniyan. Ebo riru je ona
pataki ti awon babalawo ma n gba be awon
irunmole fun awon omo eniyan. Bi ko ba si nidi, obinrin ki i je Kumolu. Eniti o ba
ni isoro lori oro ara re ni yo to babalawo lo fun ayewo ti Ifa Olokun yo si so
n kan ti yo se fun un. Bi o ba je wipe odu Osa meji lo yo fun oluware re loju opon, eleyi tumo si wipe ki iru eni bee
lo se etutu fun awon agbalagba. Awon babalawo ni yo so etutu ti o ba leto lati
se. Olorun oba ko ni je ka a rija aye
nitori eniti ija o ba lo ma n
pera re lokunrin. Atipe eniti Sango ba soju e wole, ko o ni ba won bu oba
koso. Bi awon aje ba n di eniyan lowo, oro onitohun ko ni roju beeni ko ni raye. Ki n kan to rogbo fun oluwa re, o
ni lati se ipese fun awon agba. Leyinti Ifa ba ti so ohun ti awon agba yo gba,
oru ni won yo fi ebo gbigbe si. Awon babalawo le se ipese yi laisi eniti o wa be
won nise nibe. Nigba miran ewe, eniti won fe ba be awon agba ni lati wa nibe nitori
oju awo ni awo fi n gba obe. Ohun kan pataki ti awon eniyan ni lati mo ni wipe
bi aje ba n di eniyan lowo ni Sokoto, bi o ba salo si Kafansa, owo awon agba
ni onitohun si wa.
 |
EBO FUN AWON AJE |
Iranse Olodumare ni awon Aje je, won si le mu enikeni ti won
ba fe nitori olopa Olorun ni won. Eniti won ba mu, ayafi ki oluwa re ma bebe fun itusile. Bi Eledumare se ni agbara ni ode orun ni awon Aje ati Oso naa ni agbara
nile aye. Olodumare si n lo won lori awa omo eniyan ki a le mo bi ohun ti
lagbara to Lori wa. Enikeni ti o ba so wipe ti awon agba bawo, onitohun yo o jeyan e
nisu, yo o si tun joka e lelubo. Sugbon ti awon babalawo ba ti se etutu ti o
to fun oluwa re ti awon agba si gbaa, adura onitohun ti gba niyen. Leyin eyi,
gbogbo ona onitohun yo bere si ni roju ati raye pelu. Onitohun yo wa dupe lowo
babalawo, babalawo naa yo ma yin Ifa re.
EGUNGUN ALARINJO NI AMULUDUN LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN
Ni igba atijo ni aye awon baba wa, eegun kan wa ti oruko re n je Amuludun. Eegun agba ni Amuludun je, o si tun un lokiki pupo nitori o ma a n pidan. Yato si eyi, o tun un mo ijo jo daradara. Eleyi jeki gbogbo awon ara abule feran re pupo. Ni ojo ti Amuludun ba fe pidan, opolopo awon eniyan yo o ti pejo
 |
Eegun Amuludun |
lati wa wo iran. Bi eegun ba ti n jade bo si agbo idan ni awon onilu re yo ti ma fi ilu ki i. Eegun funrare yo ma pesa beeni yo si ma korin pelu. Bi idan ba ti bere, bi Amuludun ti n di aja beeni yo ma di ere ki o to pada wa di egungun ni igbeyin. Bi eyi ti n sele lowo ni awon eniyan yo ma nawo fun un eegun ti won yo o si ma fi idunnu won han si pelu. Ojo ti Amuludun ba a n pidan ma a n larinrin pupo nitori bi awon eniyan ti n yesi lotun beeni won yo o si ma a yesi losi. Bi eegun ba ti pidan tan ni abule re, yo gbaradi lati rin irin ajo lo si awon abule to wa ni itosi re ati awon abule ti o jina si won lati lo pidan. Eleyi ni yo o
 |
Eegun |
se fun gbagede osu mefa tabi ju bee lo ki o to pada wa sile. Bi o ba ti pada wa sile ni yo tun ti beresi ni gbaradi fun irin ajo miran nipa kiko orin tuntun, ijo tuntun, esa ati ilu tuntun. Gbogbo awon owo ati ebun ti Amuludun ba mu wale lati irin ajo, ohun ati awon alaini ni abule ni won yo o jo na tan nitori eegun to laanu ni. Bi eegun Amuludun pelu awon emewa re yo se ma a ti abule de abule, ileto de ileto fun idan oniruuru pipa fun awon ogunlogo eniyan ti okiki re yo o si n kan kaakiri. Iru arikose ni awon alarinjo erele tiata ati ti itage beresi ni mulo lati odo Eegun Amuludun fun un ise ati ise won. Awon eleegun alarinjo ni won koko bere ise tiata ni igba laelae.
 |
Olori Eegun ati Olalekan Oduntan |
Eleyi yo o fihan wa wipe asa ati use awa omo Yoruba dara pupo, ohun ti o si ye ki a ma a gbe laruge ni. Ni aye ode oni, opolopo to wa lati idile eleegun ti so ile nu nitori esin kan tabi imiran, a n fi itan yi tawaji lati ma jeki awon asa ati ise wa parun nitori ohun a ni la a gbe laruge. O dowo emi ati iwo. Awon Oyinbo le ni gbogbo n kan lorisirisi, won ko leegun, won ko nigunnuko beeni

won ko lagemo, iran awa Yoruba lo ni gbogbo awon n kan wonyi. Ni ipari oro mi, no fe ki gbogbo awa omo Yoruba mase gbagbe orirun wa nitori eniti ko ba mo ibiti o ti n bo, kole mo ibiti o n lo. Eni ba sole nu, o sapo iya ko!! O dabo!!!
ODUN
EGUNGUN NI ILE YORUBA , LATI OWO
OLALEKAN ODUNTAN.
 |
Chief Babatunde Ishola Lasisi Omitowo [Otun Baale Orile Shomolu] |
Odun Egungun ni ile
Yoruba je asiko kan pataki ti ko se fi owo roti seyin nitori awon Yoruba gbagbo
wipe Orisa n la kan ni Eegun je. Bi won ba ti dajo sona ni awon eleegun ati
awon atokun ti yo o tele yo ti ma gbaradi de egungun won. Koda, alagbaa eegun
koni geyin ninu ipalemo naa. Ara orun ni
awon Yoruba gbagbo wipe egungun je. Ki o to di ojo ti
 |
Eegun Adakeja |
egungun yo o jade
ni awon babalawo yo ti difa lati se etutu ti o ba leto, leyin eyi egungun yo
de lati orun. Inu igbale ni egungun ma n de si, awon oloye bi i alagbaa ati
atigbale ni yo o si gba lalejo. Awon obinrin ko gbodo wo igbale eegun, koda
iya agan. Awon okunrin ni won ma
 |
Awon onworan |
a n meegun jade lati igbale wa sita ti awon
iya agan yo si joko de ni ita. Bi egungun
ba ti jade sita, o ni lati lo fi ori bale fun un awon oloye obinrin yi lati
gba adura lenu won ki o ma a sere kaakiri igboro. Aso olorisirisi awo ni egungun
ma n wo wa saye, awon atokun si ma a n fun won ni orisirisi oruko pelu. Bi egungun ba jade sita, a a
 |
Awon emewa eegun |
pawo wale, opolopo
owo ni awon eniyan ma n bun eegun ti o ba wa lode. Agaga bi eegun ba tie wa lo
jo o re, n se ni ori awon atokun yo o ma
wu nitoriwipe owo ti de. Leyinti egungun ba ti jade kuro ni igbale tan, ode wiwo
ni o ku. Yo o si ma ti ibi kan lo si ibomiran nipa sise adura fun un awon eniyan beeni won o si ma a fun un ni
owo ati awon ebun lorisirisi pelu. Iran eegun ma a n dun lati
wo gan an agaga to ba je eegun to mojojo
daradara. Awon onilu ki i gbeyin lojo odun eegun nitori bi won ti n se gudugudu
meje beeni won o ma a se yaayaa mefa lori ilu won. Bi won ba fe bo egungun, won
a ma a fi eko ati oole, akuko adiye, oti sinaapu ati obi bo. Obinrin ko gbodo
de ojubo egungun. O dabo!!!
Copyrights: © Olalekan Oduntan 2014.
FIFI EWE ATI EGBO SE
IWOSAN NI ILE YORUBA, LATI OWO OLALEKAN
ODUNTAN.
 |
Arabirin Toyin Serifat Gbadamosi
[AWONISAN ATI ELEWE OMO]
|
 |
Awon agunmu orisirisi |
Ni igba iwase, ewe ati egbo ni awon baba wa
fi n se iwosan, a si ma a je bi idan fun won. Aisan orisirisi ni won a ma fi ewe
ati egbo wo bi i arun Iba, roparose, iju , arun ibalopo, eje riru , ito sugaa,
ato to san ati bee bee lo. Orisa ti o ni ewe ati egbo ni won n pe ni Olubikin. Itan so wipe nigbati Orunmila wa
laye, asiko yi kannaa ni
 |
Awon agunmu lorisirisi |
Olubikin n be. Bi Orunmila se n fi Ifa pa itu fun awon
omo araye beeni Olubikin naa n fi ewe ati egbo se iwosan fun awon omo
eniyan. Awon mejeeji si n gburo ara won nipa ara ti won n da ni
 |
Awon ileke Ifa |
ilu.Sugbon ni ojo
kan, Olubikin lo ba Orunmila nile wipe
ki o ko ohun ni Ifa, o si gba lati
ko. Awon mejeeji ko eko lowo ara won. Ni asiko yi ni Ifa
wo inu ewe ati egbo, ti ewe ati egbo naa si wo inu Ifa. Eyi ni itan bi
Orunmila ati Olubikin se n ran ara won lowo titi di oni yi. Alejo mi arabinrin
Toyin Serifat Gbadamosi je elewe
omo, ti o si n fi ewe ati egbo se iwosan fun
 |
Awon ewe ati egbo fun iwosan |
awon eniyan. Awon
aisan tabi arun ti o ma a n wo po bi i atosi egbe, ito sugaa, airomobi, eje
riru, ako jedijedi ati bee bee lo. Toyin Gbadamosi ti wa ninu ise yi lati bi
odun mejila seyin, o si ko ise yi ni odo iya re agba ti o ti di oloogbe ki o to
di wipe o n da ise naa se. O feran lati
ma a dun awon eniyan ninu nipa sise
 |
Eja ojiji |
iwosan fun aisan tabi
arun won. Opolopo agan ni o ti ri omo bi ni odo re, ti awon alatosi ati onito
sugaa si n ri iwosan pelu. Bi o ba fe se iwosan fun enikeni, yo o koko ni ki
onitohun lo seayewo daradara ni ile iwosan igbalode ki o si gba iwe wa fun
aridaju ki o to se itoju fun un. Leyin igbati o ba ti toju onitohun tan, yo o
tun pada lo sile iwosan, iwadi yo o si wipe ara re ti ya.Ko si aisan
naa ti ewe ati egbo ko le se iwosan fun ayafi bi eniyan ko ba a mo ni. Nibiti
won gbe ti n taja ni oja Alade ni iso awon elewe omo, ofin wa pe enikeni ko
gbodo ta ewe, egbo, eku, eye tabi eja ti ko ba mo nipa re. Enikeni ti won ba
mu fun irufe iwa bayi, yo o san owo itanran, awon alase oja yo si tun so iso re pelu. Ise tita ewe omo ti
yato si ti igba kan nitori ara orisirisi ni awon
elewe omo n fi ewe ati egbo da ni ode iwoyi. Ni ipari oro mi, a be awon ijoba wa
ki won ma fun awon elewe omo, awon
babalawo ati onisegun wa laye lati ran awon alaisan tabi alarun ti ogun Oyinbo
ko le ran lowo. Eleyi yo le jeki ogun ibile ma se iranlowo fun ogun Oyinbo. O
dabo!!!
 |
AWON IKOKO AGBO |
 |
AWON IKOKO ASEJE TABI FUN EBO |
AMULUDUN NI ILU JE
FUN AWA OMO ARAYE , LATI OWO OLALEKAN ODUNTAN.
All Sorts of ARTs Inspire The Many Future-Visions Of The Human-Social-World & A Natural-Earth.
ReplyDeleteI think that At Present Time The World Many Situations Comes Difficult Turning Time. In My young Time My A College teacher Taught me That We have responsibility To Build Up AND Leave A What Case Society and World AND The Nature-Earth.
Enter your comment...eseun adupe konireyin ooo
ReplyDeleteAlafia olalekan oduntan I am neiko Lane and I'm over here in America in the georgia state and I have a babalawo in southcarolina his name is Taiwo Akintobi and a good priest but I need some God parents I would like to meet with you one day I am a leo August 14,1988 7065723235 that's my mother number her name is stephanie
ReplyDeletePlease
ReplyDeleteJe vous félicite énormément pour le travail abattu. Courage et persévérance à vous
ReplyDeleteEse gan ni fun eko yi. Olodumare aso agbara yin dotun.
ReplyDelete